Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 69:1-7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Gbà mí, Ọlọrun,nítorí omi ti mù mí dé ọrùn.

2. Mo ti rì sinu irà jíjìn,níbi tí kò ti sí ohun ìfẹsẹ̀tẹ̀;mo ti bọ́ sinu ibú,omi sì ti bò mí mọ́lẹ̀.

3. Mo sọkún títí àárẹ̀ mú mi,ọ̀nà ọ̀fun mi gbẹ,ojú mi sì di bàìbàì,níbi tí mo ti dúró, tí mò ń wo ojú ìwọ Ọlọrun mi.

4. Àwọn tí ó kórìíra mi láìnídìí pọ̀,wọ́n pọ̀ ju irun orí mi lọ.Àwọn tí ó fẹ́ pa mí run lágbára.Àwọn ọ̀tá mi ń parọ́ mọ́ mi,àwọn nǹkan tí n kò jíni wọ́n ní kí n fi dandan dá pada.

5. Ọlọrun, o mọ ìwà òmùgọ̀ mi,àwọn àṣìṣe mi kò sì fara pamọ́ fún ọ.

6. Má tìtorí tèmi dójúti àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ,OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun,má sì tìtorí mi sọ àwọn tí ń wá ọ di ẹni àbùkù,Ọlọrun Israẹli.

7. Nítorí tìrẹ ni mo ṣe di ẹni ẹ̀gàn,tí ìtìjú sì bò mí.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 69