Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 68:1-19 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Kí Ọlọrun dìde, kí àwọn ọ̀tá rẹ tú ká.Kí àwọn tí ó kórìíra rẹ̀ sá níwájú rẹ̀.

2. Bí èéfín tií pòórá,bẹ́ẹ̀ ni kí wọn parẹ́;bí ìda tií yọ́ níwájú iná,bẹ́ẹ̀ ni kí àwọn eniyan burúkú parun níwájú Ọlọrun.

3. Ṣugbọn kí inú àwọn olódodo máa dùn,kí wọn máa yọ̀ níwájú Ọlọrun;kí wọn máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀.

4. Ẹ kọrin sí Ọlọrun, ẹ kọ orin ìyìn sí orúkọ rẹ̀,ẹ pòkìkí ẹni tí ń gun ìkùukùu lẹ́ṣin.OLUWA ni orúkọ rẹ̀;ẹ máa yọ̀ níwájú rẹ̀.

5. Baba àwọn aláìníbaba ati olùgbèjà àwọn opó ni Ọlọrun,ní ibùgbé rẹ̀ mímọ́.

6. Ọlọrun, olùpèsè ibùjókòó fún àlejò tí ó nìkan wà;ẹni tí ó kó àwọn ẹlẹ́wọ̀n jáde sinu ìdẹ̀ra,ṣugbọn ó sì fi àwọn ọlọ̀tẹ̀ sílẹ̀ ninu ilẹ̀ gbígbẹ.

7. Ọlọrun, nígbà tí ò ń jáde lọ níwájú àwọn eniyan rẹ,nígbà tí ò ń yan la aṣálẹ̀ já,

8. ilẹ̀ mì tìtì, ọ̀run pàápàá rọ òjò,níwájú Ọlọrun, Ọlọrun Sinai,àní, níwájú Ọlọrun Israẹli.

9. Ọlọrun, ọpọlọpọ ni òjò tí o rọ̀ sílẹ̀;o sì mú ilẹ̀ ìní rẹ tí ó ti gbẹ pada bọ̀ sípò.

10. Àwọn eniyan rẹ rí ibùgbé lórí rẹ̀;Ọlọrun, ninu oore ọwọ́ rẹ, o pèsè fún àwọn aláìní.

11. OLUWA fọhùn,ogunlọ́gọ̀ sì ni àwọn tí ó kéde ọ̀rọ̀ rẹ̀.

12. Gbogbo àwọn ọba ni ó sá tàwọn tọmọ ogun wọn;àwọn obinrin tí ó wà nílé,

13. ati àwọn tí ó wà ní ibùjẹ ẹran rí ìkógun pín:fadaka ni wọ́n yọ́ bo apá ère àdàbà;wúrà dídán sì ni wọ́n yọ́ bo ìyẹ́ rẹ̀.

14. Nígbà tí Olodumare tú àwọn ọba ká,ní òkè Salimoni, yìnyín bọ́.

15. Áà! Òkè Baṣani, òkè ńlá;Áà! Òkè Baṣani, òkè olórí pupọ.

16. Ẹ̀yin òkè olórí pupọ,kí ló dé tí ẹ̀ ń fi ìlara wo òkè tí Ọlọrun fẹ́ràn láti máa gbé,ibi tí OLUWA yóo máa gbé títí lae?

17. OLUWA sọ̀kalẹ̀ láti òkè Sinai sí ibi mímọ́ rẹ̀pẹlu ẹgbẹẹgbẹrun lọ́nà ẹgbẹrun kẹ̀kẹ́ ogun,ẹgbẹẹgbẹrun lọ́nà ẹgbẹrun.

18. Ó gun òkè gíga,ó kó àwọn eniyan nígbèkùn;ó gba ẹ̀bùn lọ́wọ́ àwọn eniyan,ati lọ́wọ́ àwọn ọlọ̀tẹ̀ pàápàá.OLUWA Ọlọrun yóo máa gbébẹ̀.

19. Ìyìn ni fún OLUWA, Ọlọrun ìgbàlà wa,tí ń bá wa gbé ẹrù wa lojoojumọ.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 68