Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 66:11-19 BIBELI MIMỌ (BM)

11. O jẹ́ kí á bọ́ sinu àwọ̀n;o sì di ẹrù wúwo lé wa lórí.

12. O jẹ́ kí àwọn eniyan máa gùn wá lórí mọ́lẹ̀,a ti la iná ati omi kọjá;sibẹsibẹ o mú wa wá sí ibi tí ilẹ̀ ti tẹ́jú.

13. N óo wá sinu ilé rẹ pẹlu ọrẹ ẹbọ sísun;n óo sì san ẹ̀jẹ́ mi fún ọ.

14. Ẹ̀jẹ́ tí mo jẹ́,tí mo sì fi ẹnu mi sọ nígbà tí mo wà ninu ìpọ́njú.

15. N óo fi ẹran àbọ́pa rú ẹbọ sísun sí ọ,èéfín ẹbọ àgbò yóo rú sókè ọ̀run,n óo fi akọ mààlúù ati òbúkọ rúbọ.

16. Ẹ wá gbọ́, gbogbo ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù Ọlọrun,n óo sì ròyìn ohun tí ó ṣe fún mi.

17. Mo ké pè é,mo sì kọrin yìn ín.

18. Bí mo bá gba ẹ̀ṣẹ̀ láyè ní ọkàn mi,OLUWA ìbá tí gbọ́ tèmi.

19. Ṣugbọn nítòótọ́, Ọlọrun ti gbọ́;ó sì ti dáhùn adura mi.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 66