Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 65:4-11 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí o yàn,tí o mú wá sí ọ̀dọ̀ rẹ,láti máa gbé inú àgbàlá rẹ.Àwọn ire inú ilé rẹ yóo tẹ́ wa lọ́rùn,àní, àwọn ire inú tẹmpili mímọ́ rẹ!

5. Iṣẹ́ òdodo tí ó bani lẹ́rù ni o fi dá wa lóhùn,Ọlọrun olùgbàlà wa.Ìwọ ni gbogbo àwọn tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé gbẹ́kẹ̀lé,ati àwọn tí wọn wà lórí omi òkun ní ọ̀nà jíjìn réré.

6. Ìwọ tí o fi agbára fi ìdí àwọn òkè ńlá múlẹ̀;tí o sì fi agbára di ara rẹ ní àmùrè.

7. O mú híhó òkun dákẹ́ jẹ́ẹ́,ariwo ìgbì wọn rọlẹ̀ wọ̀ọ̀;o sì paná ọ̀tẹ̀ àwọn eniyan.

8. Àwọn tí ń gbé ìpẹ̀kun ayé sì ń bẹ̀rùnítorí àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ;o mú kí àwọn eniyan, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ rẹ̀, hó ìhó ayọ̀.

9. Ò ń ṣìkẹ́ ayé, o sì ń bomi rin ín,o mú kí ilẹ̀ jí kí ó sì lẹ́tù lójú;o mú kí omi kún inú odò ìwọ Ọlọrun,o mú kí ọkà hù lórí ilẹ̀;nítorí pé bẹ́ẹ̀ ni o ṣe ṣètò rẹ̀.

10. O bomi rin poro oko rẹ̀ lọpọlọpọ,o ṣètò àwọn ẹsẹ̀ rẹ̀;o rọ òjò tó mú kí ilẹ̀ rọ̀,o sì mú kí ohun ọ̀gbìn rẹ̀ dàgbà.

11. O mú kí ìkórè oko pọ̀ yanturu ní òpin ọdún;gbogbo ipa ọ̀nà rẹ sì kún fún ọpọlọpọ ìkórè oko.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 65