Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 60:1-12 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ọlọrun, o ti kọ̀ wá sílẹ̀,o ti wó odi wa;o ti bínú, dákun, mú wa bọ̀ sípò.

2. O ti mú kí ilẹ̀ mì tìtì;o ti mú kí ó yanu;dí gbogbo ibi tí ilẹ̀ ti ya, nítorí pé ó ń mì.

3. O ti jẹ́ kí àwọn eniyan rẹ ní ọpọlọpọ ìnira,o ti fún wa ní ọtí mu tóbẹ́ẹ̀ tí à ń ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n.

4. O ti ta àsíá ogun fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ,kí wọ́n baà lè rí ààbò lọ́wọ́ ọfà ọ̀tá.

5. Kí á lè gba àyànfẹ́ rẹ là,fi ọwọ́ agbára rẹ ṣẹgun fún wa,kí o sì dá wa lóhùn.

6. Ọlọrun ti sọ̀rọ̀ ninu ilé mímọ́ rẹ̀,ó ní, “Tayọ̀tayọ̀ ni n óo fi pín Ṣekemu,n óo sì pín àfonífojì Sukotu.

7. Tèmi ni Gileadi, tèmi sì ni Manase;Efuraimu ni àkẹtẹ̀ àṣíborí mi,Juda sì ni ọ̀pá àṣẹ mi.

8. Moabu ni ìkòkò ìwẹsẹ̀ mi;lórí Edomu ni n óo bọ́ bàtà mi lé;n óo sì hó ìhó ayọ̀ ìṣẹ́gun lórí Filistia.”

9. Ta ni yóo mú mi wọ inú ìlú olódi náà?Ta ni yóo mú mi lọ sí Edomu?

10. Ọlọrun, o kò ha ti kọ̀ wá sílẹ̀?Ọlọrun, o ò bá àwọn ọmọ ogun wa jáde lọ sójú ogun mọ́.

11. Ràn wá lọ́wọ́, bá wa gbógun ti àwọn ọ̀tá wa,nítorí pé asán ni ìrànlọ́wọ́ eniyan.

12. Pẹlu àtìlẹ́yìn Ọlọrun a óo ṣe akin,nítorí òun ni yóo tẹ àwọn ọ̀tá wa mọ́lẹ̀.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 60