Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 6:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA, má fi ibinu bá mi wí;má sì fi ìrúnú jẹ mí níyà.

2. Ṣàánú mi, OLUWA, nítorí àárẹ̀ mú ọkàn mi,OLUWA, wò mí sàn nítorí ara ń ni mí dé egungun.

3. Ọkàn mi kò balẹ̀ rárá,yóo ti pẹ́ tó, OLUWA, yóo ti pẹ́ tó?

4. OLUWA, pada wá gbà mí,gbà mí là nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀.

5. Nítorí kò sí ẹni tí yóo ranti rẹ lẹ́yìn tí ó bá ti kú.Àbí, ta ló lè yìn ọ́ ninu isà òkú?

6. Ìkérora dá mi lágara:ní òròòru ni mò ń fi omijé rẹ ẹní mi;tí mò ń sunkún tí gbogbo ibùsùn mi ń tutù.

7. Ìbànújẹ́ sọ ojú mi di bàìbàì,agbára káká ni mo fi lè ríran nítorí ìnilára àwọn ọ̀tá.

8. Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin oníṣẹ́ ibi,nítorí OLUWA ti gbọ́ ìró ẹkún mi.

9. OLUWA ti gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi,OLUWA ti tẹ́wọ́gba adura mi.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 6