Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 6:1-10 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA, má fi ibinu bá mi wí;má sì fi ìrúnú jẹ mí níyà.

2. Ṣàánú mi, OLUWA, nítorí àárẹ̀ mú ọkàn mi,OLUWA, wò mí sàn nítorí ara ń ni mí dé egungun.

3. Ọkàn mi kò balẹ̀ rárá,yóo ti pẹ́ tó, OLUWA, yóo ti pẹ́ tó?

4. OLUWA, pada wá gbà mí,gbà mí là nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀.

5. Nítorí kò sí ẹni tí yóo ranti rẹ lẹ́yìn tí ó bá ti kú.Àbí, ta ló lè yìn ọ́ ninu isà òkú?

6. Ìkérora dá mi lágara:ní òròòru ni mò ń fi omijé rẹ ẹní mi;tí mò ń sunkún tí gbogbo ibùsùn mi ń tutù.

7. Ìbànújẹ́ sọ ojú mi di bàìbàì,agbára káká ni mo fi lè ríran nítorí ìnilára àwọn ọ̀tá.

8. Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin oníṣẹ́ ibi,nítorí OLUWA ti gbọ́ ìró ẹkún mi.

9. OLUWA ti gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi,OLUWA ti tẹ́wọ́gba adura mi.

10. Ojú yóo ti gbogbo àwọn ọ̀tá mi;ìdààmú ńlá yóo bá wọn,wọn óo sá pada,ojú yóo sì tì wọ́n lójijì.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 6