Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 59:6-17 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Ní alaalẹ́, wọn á pada wá,wọn á máa hu bí ajá, wọn a sì máa kiri ìlú.

7. Ẹ gbọ́ ohun tí wọn ń sọ jáde lẹ́nu,ẹ wo ahọ́n wọn bí idà;wọ́n sì ń wí ninu ara wọn pé, “Ta ni yóo gbọ́ ohun tí à ń sọ?”

8. Ṣugbọn ìwọ OLUWA ń fi wọ́n rẹ́rìn-ín,o sì ń fi gbogbo orílẹ̀-èdè ṣe yẹ̀yẹ́.

9. Ọlọrun, agbára mi, ojú rẹ ni mò ń wò,nítorí ìwọ, Ọlọrun, ni odi mi.

10. Ọlọrun mi óo wá sọ́dọ̀ mi ninu ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀;Ọlọrun óo fún mi ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá mi.

11. Má pa wọ́n, kí àwọn eniyan mi má baà gbàgbé;fi ọwọ́ agbára rẹ mì wọ́n,ré wọn lulẹ̀, OLUWA, ààbò wa!

12. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n fi ẹnu wọn dá,àní, nítorí ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ẹnu wọn sọ,jẹ́ kí ìgbéraga wọn kó bá wọn.Nítorí èpè tí wọ́n ṣẹ́ ati irọ́ tí wọ́n pa,

13. fi ibinu pa wọ́n run.Pa wọ́n run kí wọn má sí mọ́,kí àwọn eniyan lè mọ̀ pé Ọlọrun jọba lórí Jakọbu,ati títí dé òpin ayé.

14. Ní alaalẹ́ wọn á pada wáwọn á máa hu bí ajá, wọn á sì máa kiri ìlú.

15. Wọn á máa fẹsẹ̀ wọ́lẹ̀, wọn á máa wá oúnjẹ kiri,bí wọn ò bá sì yó wọn á máa kùn.

16. Ṣugbọn èmi ó kọrin ìyìn agbára rẹ;n óo kọrin sókè lówùúrọ̀, nípa ìfẹ́ rẹ tíkì í yẹ̀.Nítorí ìwọ ni o ti jẹ́ odi miìwọ sì ni ààbò mi nígbà ìpọ́njú.

17. Ọlọrun, agbára mi, n óo kọ orin ìyìn fún ọ,nítorí ìwọ, Ọlọrun, ni odi mi,Ọlọrun tí ó ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn mí.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 59