Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 58:4-11 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Wọ́n ní oró bí oró ejò,wọ́n dití bíi paramọ́lẹ̀ tí ó di etí ara rẹ̀,

5. kí ó má baà gbọ́ ohùn afunfèrè,tabi ìpè adáhunṣe.

6. Kán eyín mọ́ wọn lẹ́nu, Ọlọrun;OLUWA! Yọ ọ̀gàn àwọn ẹgbọ̀rọ̀ kinniun.

7. Jẹ́ kí wọ́n rá, kí wọn ṣàn lọ bí omi;kí á tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ bíi koríko, kí wọn sì rọ.

8. Kí wọn dàbí ìgbín tí a tẹ̀ ní àtẹ̀rẹ́, tí ó domi,ati bí òkúmọ tí kò fojú kan ìmọ́lẹ̀ ayé rí.

9. Lójijì, a ó ké eniyan burúkú lulẹ̀;ìjì ibinu Ọlọrun yóo sì gbá wọn lọ.

10. Olódodo yóo yọ̀ nígbà tí ẹ̀san bá ń ké,yóo fi ẹsẹ̀ wọ́ àgbàrá ẹ̀jẹ̀ àwọn eniyan burúkú.

11. Àwọn eniyan yóo wí nígbà náà pé,“Nítòótọ́, èrè ń bẹ fún olódodo;nítòótọ́, Ọlọrun ń bẹ tí ń ṣe ìdájọ́ ayé.”

Ka pipe ipin Orin Dafidi 58