Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 56:4-13 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Ọlọrun, mo yìn ọ́ fún ọ̀rọ̀ rẹ,ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé láìbẹ̀rù;kí ni eniyan ẹlẹ́ran ara lè fi mí ṣe?

5. Tọ̀sán-tòru ni wọ́n ń da ọ̀rọ̀ mi rú;ibi ni gbogbo èrò tí wọn ń gbà sí mi.

6. Wọ́n kó ara wọn jọ, wọ́n sápamọ́,wọ́n ń ṣọ́ ìrìn ẹsẹ̀ mi,bí wọn ṣé ń dọdẹ ẹ̀mí mi.

7. Nítorí náà, san ẹ̀san ẹ̀ṣẹ̀ wọn fún wọn;ninu ibinu rẹ, Ọlọrun, ré àwọn eniyan yìí lulẹ̀.

8. O sá mọ gbogbo ìdààmú mi;ati bí omijé mi ti pọ̀ tó,wọ́n ṣá wà ní àkọsílẹ̀ ninu ìwé rẹ.

9. A óo lé àwọn ọ̀tá mi padaní ọjọ́ tí mo bá ké pè ọ́.Mo mọ̀ dájú pé Ọlọrun ń bẹ fún mi.

10. Ọlọrun, tí mo yin ọ̀rọ̀ rẹ̀,OLUWA, tí mo yin ọ̀rọ̀ rẹ̀;

11. Ọlọrun ni mo gbẹ́kẹ̀lé láìbẹ̀rù.Kí ni eniyan ẹlẹ́ran ara lè fi mí ṣe?

12. Èmi óo san ẹ̀jẹ́ mi fún ọ, Ọlọrun;n óo sì mú ẹbọ ọpẹ́ wá fún ọ.

13. Nítorí pé o ti gba ẹ̀mí mi lọ́wọ́ ikú,o gbà mí, o kò jẹ́ kí n kọsẹ̀,kí n lè máa rìn níwájú Ọlọrunninu ìmọ́lẹ̀ ìyè.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 56