Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 56:1-10 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ṣàánú mi, Ọlọrun, nítorí pé àwọn eniyan ń lépa mi;ọ̀tá gbógun tì mí tọ̀sán-tòru.

2. Àwọn ọ̀tá ń lépa mi tọ̀sán-tòru,ọpọlọpọ ní ń bá mi jà tìgbéraga-tìgbéraga.

3. Nígbà tí ẹ̀rù bá ń bà mí,èmi yóo gbẹ́kẹ̀lé ọ.

4. Ọlọrun, mo yìn ọ́ fún ọ̀rọ̀ rẹ,ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé láìbẹ̀rù;kí ni eniyan ẹlẹ́ran ara lè fi mí ṣe?

5. Tọ̀sán-tòru ni wọ́n ń da ọ̀rọ̀ mi rú;ibi ni gbogbo èrò tí wọn ń gbà sí mi.

6. Wọ́n kó ara wọn jọ, wọ́n sápamọ́,wọ́n ń ṣọ́ ìrìn ẹsẹ̀ mi,bí wọn ṣé ń dọdẹ ẹ̀mí mi.

7. Nítorí náà, san ẹ̀san ẹ̀ṣẹ̀ wọn fún wọn;ninu ibinu rẹ, Ọlọrun, ré àwọn eniyan yìí lulẹ̀.

8. O sá mọ gbogbo ìdààmú mi;ati bí omijé mi ti pọ̀ tó,wọ́n ṣá wà ní àkọsílẹ̀ ninu ìwé rẹ.

9. A óo lé àwọn ọ̀tá mi padaní ọjọ́ tí mo bá ké pè ọ́.Mo mọ̀ dájú pé Ọlọrun ń bẹ fún mi.

10. Ọlọrun, tí mo yin ọ̀rọ̀ rẹ̀,OLUWA, tí mo yin ọ̀rọ̀ rẹ̀;

Ka pipe ipin Orin Dafidi 56