Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 55:6-15 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Mo ní, “Èmi ìbá ní ìyẹ́ bí àdàbà!Ǹ bá fò lọ, ǹ bá lọ sinmi.

7. Áà! Ǹ bá lọ jìnnà réré,kí n lọ máa gbé inú ijù;

8. ǹ bá yára lọ wá ibi ààbòkúrò lọ́wọ́ afẹ́fẹ́ líle ati ìjì.”

9. Da èrò wọn rú, OLUWA,kí o sì dà wọ́n lédè rú;nítorí ìwà ipá ati asọ̀ pọ̀ ninu ìlú.

10. Tọ̀sán-tòru ni wọ́n ń yí orí odi rẹ̀ ká;ìwà ìkà ati ìyọnu ni ó sì pọ̀ ninu rẹ̀.

11. Ìparun wà ninu rẹ̀;ìnilára ati ìwà èrú kò sì kúrò láàrin ìgboro rẹ̀.

12. Bí ó bá ṣe pé ọ̀tá ní ń gàn mí,ǹ bá lè fara dà á.Bí ó bá ṣe pé ẹni tí ó kórìíra mi ní ń gbéraga sí mi,ǹ bá fara pamọ́ fún un.

13. Ṣugbọn ìwọ ni; ìwọ tí o jẹ́ irọ̀ mi,alábàárìn mi, ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́.

14. À ti jọ máa sọ ọ̀rọ̀ dídùndídùn pọ̀ rí;a sì ti jọ rìn ní ìrẹ́pọ̀ ninu ilé Ọlọrun.

15. Jẹ́ kí ikú jí àwọn ọ̀tá mi pa;kí wọ́n lọ sinu isà òkú láàyè;kí wọ́n wọ ibojì lọ pẹlu ìpayà.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 55