Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 55:14-21 BIBELI MIMỌ (BM)

14. À ti jọ máa sọ ọ̀rọ̀ dídùndídùn pọ̀ rí;a sì ti jọ rìn ní ìrẹ́pọ̀ ninu ilé Ọlọrun.

15. Jẹ́ kí ikú jí àwọn ọ̀tá mi pa;kí wọ́n lọ sinu isà òkú láàyè;kí wọ́n wọ ibojì lọ pẹlu ìpayà.

16. Ṣugbọn èmi ké pe Ọlọrun;OLUWA yóo sì gbà mí.

17. Mò ń ráhùn tọ̀sán-tòru,mo sì ń kérora; OLUWA óo gbọ́ ohùn mi.

18. Yóo yọ mí láìfarapa,ninu ogun tí mò ń jà,nítorí ọ̀pọ̀ ni àwọn tí wọ́n dojú kọ mí,tí wọn ń bá mi jà.

19. Ọlọrun tí ó gúnwà láti ìgbàanì yóo gbọ́,yóo sì rẹ̀ wọ́n sílẹ̀,nítorí pé wọn kò pa ìwà wọn dà,wọn kò sì bẹ̀rù Ọlọrun.

20. Alábàárìn mi gbógun ti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀,ó yẹ àdéhùn rẹ̀.

21. Ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ dùn ju oyin lọ,bẹ́ẹ̀ sì ni ìjà ni ó wà lọ́kàn rẹ̀;ọ̀rọ̀ rẹ̀ tutù ju omi àmù lọ,ṣugbọn idà aṣekúpani ni.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 55