Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 55:11-19 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Ìparun wà ninu rẹ̀;ìnilára ati ìwà èrú kò sì kúrò láàrin ìgboro rẹ̀.

12. Bí ó bá ṣe pé ọ̀tá ní ń gàn mí,ǹ bá lè fara dà á.Bí ó bá ṣe pé ẹni tí ó kórìíra mi ní ń gbéraga sí mi,ǹ bá fara pamọ́ fún un.

13. Ṣugbọn ìwọ ni; ìwọ tí o jẹ́ irọ̀ mi,alábàárìn mi, ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́.

14. À ti jọ máa sọ ọ̀rọ̀ dídùndídùn pọ̀ rí;a sì ti jọ rìn ní ìrẹ́pọ̀ ninu ilé Ọlọrun.

15. Jẹ́ kí ikú jí àwọn ọ̀tá mi pa;kí wọ́n lọ sinu isà òkú láàyè;kí wọ́n wọ ibojì lọ pẹlu ìpayà.

16. Ṣugbọn èmi ké pe Ọlọrun;OLUWA yóo sì gbà mí.

17. Mò ń ráhùn tọ̀sán-tòru,mo sì ń kérora; OLUWA óo gbọ́ ohùn mi.

18. Yóo yọ mí láìfarapa,ninu ogun tí mò ń jà,nítorí ọ̀pọ̀ ni àwọn tí wọ́n dojú kọ mí,tí wọn ń bá mi jà.

19. Ọlọrun tí ó gúnwà láti ìgbàanì yóo gbọ́,yóo sì rẹ̀ wọ́n sílẹ̀,nítorí pé wọn kò pa ìwà wọn dà,wọn kò sì bẹ̀rù Ọlọrun.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 55