Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 54:3-7 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Nítorí pé àwọn agbéraga dìde sí mi,àwọn ìkà, aláìláàánú sì ń lépa ẹ̀mí mi;wọn kò bìkítà fún Ọlọrun.

4. Ṣugbọn Ọlọrun ni olùrànlọ́wọ́ mi,OLUWA ni ó gbé ẹ̀mí mi ró.

5. Yóo san ẹ̀san ibi fún àwọn ọ̀tá mi;OLUWA, nítorí òtítọ́ rẹ, pa wọ́n run.

6. N óo rú ẹbọ ọrẹ àtinúwá sí ọ,n óo máa yin orúkọ rẹ, OLUWA,nítorí pé ó dára bẹ́ẹ̀.

7. O ti yọ mí ninu gbogbo ìṣòro mi,mo sì ti fi ojú mi rí ìṣubú àwọn ọ̀tá mi.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 54