Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 52:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ìwọ alágbára, kí ló dé tí o fi ń fọ́nnu,kí ló dé tí ò ń fọ́nnu tọ̀sán-tòru?Ẹni ìtìjú ni ọ́ lójú Ọlọrun.

2. Ò ń pète ìparun;ẹnu rẹ dàbí abẹ tí ó mú, ìwọ alárèékérekè.

3. O fẹ́ràn ibi ju ire lọ,o sì fẹ́ràn irọ́ ju òtítọ́ lọ.

4. O fẹ́ràn gbogbo ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́,Ìwọ ẹlẹ́tàn!

5. Nítòótọ́ Ọlọrun óo bá ọ kanlẹ̀,yóo gbá ọ mú, yóo sì fà ọ́ já kúrò ninu ilé rẹ;yóo fà ọ́ tu kúrò lórí ilẹ̀ alààyè.

6. Nígbà tí àwọn olódodo bá rí i, ẹ̀rù óo bà wọ́n,wọn óo fi rẹ́rìn-ín, wọn óo sì wí pé,

7. “Wo ẹni tí ó kọ̀, tí kò fi Ọlọrun ṣe ààbò rẹ̀,ṣugbọn ó gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ rẹ̀ tí ó pọ̀,ati jamba tí ó ń ta fún ẹlòmíràn.”

8. Ṣugbọn èmi dàbí igi olifi tútùtí ń dàgbà ninu ilé OLUWA,mo gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ Ọlọrun tí kì í yẹ̀, lae ati laelae.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 52