Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 51:6-13 BIBELI MIMỌ (BM)

6. O fẹ́ràn òtítọ́ inú;nítorí náà, kọ́ mi lọ́gbọ́n ní kọ́lọ́fín ọkàn mi.

7. Fi ewé hisopu fọ̀ mí, n óo sì mọ́;wẹ̀ mí, n óo sì funfun ju ẹ̀gbọ̀n òwú lọ.

8. Fún mi ní ayọ̀ ati inú dídùn,kí gbogbo egungun mi tí ó ti rún lè máa yọ̀.

9. Mójú kúrò lára ẹ̀ṣẹ̀ mi,kí o sì pa gbogbo àìdára mi rẹ́.

10. Dá ọkàn mímọ́ sí inú mi, Ọlọrun,kí o sì fi ẹ̀mí ọ̀tun ati ẹ̀mí ìṣòótọ́ sí mi lọ́kàn.

11. Má ta mí nù kúrò lọ́dọ̀ rẹ,má sì gba Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ lọ́wọ́ mi.

12. Dá ayọ̀ ìgbàlà rẹ pada fún mi,kí o sì fi ẹ̀mí àtiṣe ìfẹ́ rẹ gbé mi ró.

13. Nígbà náà ni n óo máa kọ́ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ọ̀nà rẹ,àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yóo sì máa yipada sí ọ.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 51