Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 50:15-23 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Ẹ ké pè mí ní ọjọ́ ìṣòro;n óo gbà yín, ẹ óo sì yìn mí lógo.”

16. Ṣugbọn Ọlọrun bi àwọn eniyan burúkú pé,“Ẹ̀tọ́ wo ni ẹ níláti máa ka àwọn òfin mi,tabi láti máa mú ẹnu ba ìlànà mi?

17. Nítorí ẹ kórìíra ẹ̀kọ́;ẹ sì ti ta àṣẹ mi nù.

18. Tí ẹ bá rí olè, ẹ̀yin pẹlu rẹ̀ a dọ̀rẹ́;ẹ sì ń bá àwọn panṣaga kẹ́gbẹ́.

19. “Ọ̀rọ̀ ibi dùn lẹ́nu yín pupọ;ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn sì yọ̀ létè yín.

20. Ẹ̀ ń jókòó sọ̀rọ̀ arakunrin yín níbi:ẹ̀ ń sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ nípa ọmọ ìyá yín.

21. Gbogbo nǹkan wọnyi ni ẹ ti ṣe tí mo sì dákẹ́;ẹ wá ń rò ninu yín pé, èmi yín rí bákan náà.Ṣugbọn nisinsinyii mò ń ba yín wí,mo sì ń fi ẹ̀sùn kàn yín.

22. “Nítorí náà, ẹ fi èyí lékàn, ẹ̀yin tí ẹ gbàgbé Ọlọrun,kí n má baà fà yín ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, kò sì ní sí ẹni tí yóo gbà yín kalẹ̀.

23. Ẹni tí ó bá mu ọpẹ́ wá, tí ó fi rúbọ sí mi, ni ó bu ọlá fún mi;ẹni tí ó bá sì rìn ní ọ̀nà ẹ̀tọ́ ni èmi Ọlọrun yóo gbà là.”

Ka pipe ipin Orin Dafidi 50