Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 50:1-10 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA, Ọlọrun Alágbára ti sọ̀rọ̀:ó ké sí gbogbo ayéláti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn.

2. Ọlọrun yọ bí ọjọ́ láti Sioni,ìlú tó dára, tó lẹ́wà.

3. Ọlọrun wa ń bọ̀, kò dákẹ́:iná ajónirun ń jó níwájú rẹ̀;ìjì líle sì ń jà yí i ká.

4. Ó ké sí ọ̀run lókè;ó pe ayé pẹlu láti gbọ́ ìdájọ́ tí yóo ṣe fún àwọn eniyan rẹ̀.

5. Ó ní, “Ẹ kó àwọn olùfọkànsìn mi jọ sọ́dọ̀ mi,àwọn tí wọ́n ti fi ẹbọ bá mi dá majẹmu!”

6. Ojú ọ̀run ń kéde òdodo rẹ̀ péỌlọrun ni onídàájọ́.

7. “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin eniyan mi, n óo sọ̀rọ̀,Israẹli, n óo takò yín.Èmi ni Ọlọrun, Ọlọrun yín.

8. N kò ba yín wí nítorí ẹbọ rírú;nígbà gbogbo ni ẹ̀ ń rú ẹbọ sísun sí mi.

9. N kò ní gba akọ mààlúù lọ́wọ́ yín,tabi òbúkọ láti agbo ẹran yín.

10. Nítorí èmi ni mo ni gbogbo ẹran inú igbó,tèmi sì ni gbogbo mààlúù tó wà lórí ẹgbẹrun òkè.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 50