Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 49:3-13 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Ẹnu mi yóo sọ̀rọ̀ ọgbọ́n;àṣàrò ọkàn mi yóo sì jẹ́ ti òye.

4. N óo tẹ́tí sílẹ̀ sí òwe;n óo sì fi hapu túmọ̀ rẹ̀.

5. Kí ló dé tí n óo fi bẹ̀rù ní àkókò ìyọnu,nígbà tí iṣẹ́ ibi àwọn tí ń ṣe inúnibíni mi bá yí mi ká,

6. àwọn tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ wọn,tí wọ́n sì ń yangàn nítorí wọ́n ní ọrọ̀ pupọ?

7. Dájúdájú, kò sí ẹni tí ó le ra ara rẹ̀ pada,tabi tí ó lè san owó ìràpadà ẹ̀mí rẹ̀ fún Ọlọrun;

8. nítorí pé ẹ̀mí eniyan níye lórí pupọ.Kò sí iye tí eniyan ní tí ó le kájú rẹ̀,

9. tí eniyan lè máa fi wà láàyè títí lae,kí ó má fojú ba ikú.

10. Yóo rí i pé ikú a máa pa ọlọ́gbọ́n,òmùgọ̀ ati òpè a sì máa rọ̀run;wọn a sì fi ọrọ̀ wọn sílẹ̀ fún ẹlòmíràn.

11. Ibojì wọn ni ilé wọn títí lae,ibẹ̀ ni ibùgbé wọn títí ayérayé,wọn ìbáà tilẹ̀ ní ilẹ̀ ti ara wọn.

12. Eniyan kò lè máa gbé ninu ọlá rẹ̀ títí ayé,bí ẹranko tíí kú, ni òun náà óo kú.

13. Ìpín àwọn tí ó ní igbẹkẹle asán nìyí,òun sì ni èrè àwọn tí ọrọ̀ wọn tẹ́ lọ́rùn.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 49