Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 49:14-20 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Ikú ni ìpín wọn bí àgùntàn lásánlàsàn,ikú ni yóo máa ṣe olùṣọ́ wọn;ibojì ni wọ́n sì ń lọ tààrà.Wọn yóo jẹrà, ìrísí wọn óo sì parẹ́,Àwọn olódodo yóo jọba lórí wọn ní òwúrọ̀,ibojì ni yóo sì máa jẹ́ ilé wọn.

15. Ṣugbọn Ọlọrun yóo ra ẹ̀mí mi pada lọ́wọ́ ikúnítorí pé yóo gbà mí.

16. Má ba ara jẹ́ bí ẹnìkan bá di olówó,tí ọrọ̀ rẹ̀ ń pọ̀ sí i.

17. Nítorí pé ní ọjọ́ tí ó bá kú,kò ní mú ohunkohun lọ́wọ́ lọ;dúkìá rẹ̀ kò sì ní bá a wọ ibojì.

18. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé nígbà tí ó wà láàyè,ó rò pé Ọlọrun bukun òun,bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ayé a máa yin eniyannígbà tí nǹkan bá ń dára fún un,

19. yóo kú bí àwọn baba ńlá rẹ̀ ti kú,kò sì ní fojú kan ìmọ́lẹ̀ mọ́.

20. Eniyan kò lè máa gbé inú ọlá rẹ̀ títí ayé;bí ẹranko tíí kú, ni òun náà óo ku.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 49