Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 48:4-11 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Wò ó! Àwọn ọba kó ara wọn jọ;wọ́n jùmọ̀ gbógun tì í.

5. Nígbà tí wọ́n fojú kàn án, ẹnu yà wọ́n,ìpayà mú wọn, wọ́n sì sá;

6. ìwárìrì mú wọn níbẹ̀;ìrora sì bá wọn bí obinrin tí ń rọbí.

7. Ó fọ́ wọn bí afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn tií fọ́ ọkọ̀ Taṣiṣi.

8. Bí a ti gbọ́, bẹ́ẹ̀ gan-an ni ó rí,ní ìlú OLUWA àwọn ọmọ ogun,ní ìlú Ọlọrun wa:Ọlọrun fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ títí lae.

9. Ninu tẹmpili rẹ, Ọlọrun,à ń ṣe àṣàrò lórí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀.

10. Ọlọrun, ìyìn rẹ tàn ká,bí orúkọ rẹ ṣe tàn dé òpin ayé,iṣẹ́ rere kún ọwọ́ rẹ.

11. Jẹ́ kí inú òkè Sioni kí ó dùn,kí gbogbo Juda sì máa yọ̀nítorí ìdájọ́ rẹ.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 48