Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 48:1-11 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA tóbi, ó sì yẹ kí á máa yìn ín lọpọlọpọní ìlú Ọlọrun wa.

2. Òkè mímọ́ rẹ̀, tí ó ga, tí ó sì lẹ́wà,ni ayọ̀ gbogbo ayé.Òkè Sioni, ní àríwá, lọ́nà jíjìn réré,ìlú ọba ńlá.

3. Ninu ilé ìṣọ́ ìlú náà, Ọlọrun ti fi ara rẹ̀ hàn bí ibi ìsádi.

4. Wò ó! Àwọn ọba kó ara wọn jọ;wọ́n jùmọ̀ gbógun tì í.

5. Nígbà tí wọ́n fojú kàn án, ẹnu yà wọ́n,ìpayà mú wọn, wọ́n sì sá;

6. ìwárìrì mú wọn níbẹ̀;ìrora sì bá wọn bí obinrin tí ń rọbí.

7. Ó fọ́ wọn bí afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn tií fọ́ ọkọ̀ Taṣiṣi.

8. Bí a ti gbọ́, bẹ́ẹ̀ gan-an ni ó rí,ní ìlú OLUWA àwọn ọmọ ogun,ní ìlú Ọlọrun wa:Ọlọrun fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ títí lae.

9. Ninu tẹmpili rẹ, Ọlọrun,à ń ṣe àṣàrò lórí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀.

10. Ọlọrun, ìyìn rẹ tàn ká,bí orúkọ rẹ ṣe tàn dé òpin ayé,iṣẹ́ rere kún ọwọ́ rẹ.

11. Jẹ́ kí inú òkè Sioni kí ó dùn,kí gbogbo Juda sì máa yọ̀nítorí ìdájọ́ rẹ.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 48