Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 47:1-7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹ pàtẹ́wọ́, gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè;ẹ kọ orin ayọ̀, ẹ hó sí Ọlọrun.

2. Nítorí pé ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ ni OLUWA, Ọ̀gá Ògo,Ọba ńlá lórí gbogbo ayé.

3. Ó tẹ àwọn orílẹ̀-èdè lórí ba fún wa,ó sì sọ àwọn orílẹ̀-èdè di àtẹ̀mọ́lẹ̀ fún wa.

4. Òun ni ó yan ilẹ̀ ìní wa fún wa,èyí tí àwọn ọmọ Jakọbu, àyànfẹ́ rẹ̀, fi ń yangàn.

5. A ti gbé Ọlọrun ga pẹlu ìhó ayọ̀,a ti gbé OLUWA ga pẹlu ìró fèrè.

6. Ẹ kọ orin ìyìn sí Ọlọrun, ẹ kọ orin ìyìn;Ẹ kọ orin ìyìn sí Ọba wa, ẹ kọ orin ìyìn!

7. Nítorí Ọlọrun ni Ọba gbogbo ayé;Ẹ fi gbogbo ohun èlò ìkọrin kọ orin ìyìn!

Ka pipe ipin Orin Dafidi 47