Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 46:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ọlọrun ni ààbò ati agbára wa,olùrànlọ́wọ́ tí ó wà nítòsí nígbà gbogbo, ní ìgbà ìpọ́njú.

2. Nítorí náà ẹ̀rù kò ní bà wá bí ayé tilẹ̀ ṣídìí,bí àwọn òkè ńlá tilẹ̀ ṣípò pada, tí wọ́n bọ́ sinu òkun;

3. bí omi òkun tilẹ̀ ń hó, tí ó sì ń ru,tí àwọn òkè ńlá sì ń mì tìtìnítorí agbára ríru rẹ̀.

4. Odò kan wà tí omi rẹ̀ ń mú inú ìlú Ọlọrun dùn,ìlú yìí ni ibùgbé mímọ́ Ọ̀gá Ògo.

5. Ọlọrun wà láàrin rẹ̀,kò ní tú bẹ́ẹ̀ ni kò ní ṣí kúrò;Ọlọrun yóo ràn án lọ́wọ́ ní òwúrọ̀ kutukutu.

6. Inú àwọn orílẹ̀-èdè ń ru,àwọn ìjọba ayé ń gbọ̀n;OLUWA fọhùn, ayé sì yọ́.

7. OLUWA àwọn ọmọ ogun wà pẹlu wa;Ọlọrun Jakọbu ni ààbò wa.

8. Ẹ wá wo iṣẹ́ OLUWA,irú iṣẹ́ ribiribi tí ó ṣe láyé.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 46