Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 44:6-16 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Nítorí pé kì í ṣe ọrun mi ni mo gbẹ́kẹ̀lé;idà mi kò sì le gbà mí.

7. Ṣugbọn ìwọ ni o gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa,o sì dójú ti àwọn tí ó kórìíra wa.

8. Ìwọ Ọlọrun ni a fi ń yangàn nígbà gbogbo;a óo sì máa fi ọpẹ́ fún orúkọ rẹ títí lae.

9. Sibẹ, o ti ta wá nù o sì ti rẹ̀ wá sílẹ̀,o ò sì bá àwọn ọmọ ogun wa jáde lọ sójú ogun mọ́.

10. O ti mú kí á sá fún àwọn ọ̀tá wa lójú ogun;àwọn tí ó kórìíra wa sì fi ẹrù wa ṣe ìkógun.

11. O ti ṣe wá bí aguntan lọ́wọ́ alápatà,o sì ti fọ́n wa káàkiri àwọn orílẹ̀-èdè.

12. O ti ta àwọn eniyan rẹ lọ́pọ̀,o ò sì jẹ èrè kankan lórí wọn.

13. O ti sọ wá di ẹni ẹ̀gàn lọ́wọ́ àwọn aládùúgbò wa;a di ẹni ẹ̀sín ati ẹni yẹ̀yẹ́ lọ́dọ̀ àwọn tí ó yí wa ká.

14. O sọ wá di ẹni àmúpòwe láàrin àwọn orílẹ̀-èdè,ati ẹni yẹ̀yẹ́ láàrin gbogbo ayé.

15. Àbùkù mi wà lára mi tọ̀sán-tòru,ìtìjú sì ti bò mí.

16. Ọ̀rọ̀ àwọn apẹ̀gàn ati apeni-níjà ṣẹ mọ́ mi lára,lójú àwọn ọ̀tá mi ati àwọn tí ó fẹ́ gbẹ̀san.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 44