Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 44:13-25 BIBELI MIMỌ (BM)

13. O ti sọ wá di ẹni ẹ̀gàn lọ́wọ́ àwọn aládùúgbò wa;a di ẹni ẹ̀sín ati ẹni yẹ̀yẹ́ lọ́dọ̀ àwọn tí ó yí wa ká.

14. O sọ wá di ẹni àmúpòwe láàrin àwọn orílẹ̀-èdè,ati ẹni yẹ̀yẹ́ láàrin gbogbo ayé.

15. Àbùkù mi wà lára mi tọ̀sán-tòru,ìtìjú sì ti bò mí.

16. Ọ̀rọ̀ àwọn apẹ̀gàn ati apeni-níjà ṣẹ mọ́ mi lára,lójú àwọn ọ̀tá mi ati àwọn tí ó fẹ́ gbẹ̀san.

17. Gbogbo nǹkan yìí ló ṣẹlẹ̀ sí wa,bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò gbàgbé rẹ,bẹ́ẹ̀ ni a kò yẹ majẹmu rẹ.

18. Ọkàn wa kò pada lẹ́yìn rẹ,bẹ́ẹ̀ ni a kò yẹsẹ̀ kúrò ninu ìlànà rẹ,

19. sibẹ o fọ́ wa túútúú fún ìjẹ àwọn ẹranko,o sì fi òkùnkùn biribiri bò wá mọ́lẹ̀.

20. Bí ó bá jẹ́ pé a gbàgbé orúkọ Ọlọrun wa,tabi tí a bá bọ oriṣa,

21. ṣebí Ọlọrun ìbá ti mọ̀?Nítorí òun ni olùmọ̀ràn ọkàn.

22. Ṣugbọn nítorí tìrẹ ni wọ́n fi ń pa wá tọ̀sán-tòru,tí a kà wá sí aguntan lọ́wọ́ alápatà.

23. Para dà, OLUWA, kí ló dé tí o fi ń sùn?Jí gìrì! Má ta wá nù títí lae.

24. Kí ló dé tí o fi ń fi ojú pamọ́?Kí ló dé tí o fi gbàgbé ìpọ́njú ati ìnira wa?

25. Nítorí pé àwọn ọ̀tá ti tẹ̀ wá mọ́lẹ̀;àyà wa sì lẹ̀ mọ́lẹ̀ típẹ́típẹ́.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 44