Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 43:1-4 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Dá mi láre, Ọlọrun, kí o sì gbèjà mi,lọ́dọ̀ àwọn tí kò mọ̀ Ọ́;gbà mí lọ́wọ́ àwọn ẹlẹ́tàn ati alaiṣootọ.

2. Nítorí ìwọ ni Ọlọrun tí mo sá di.Kí ló dé tí o fi ta mí nù?Kí ló dé tí mo fi ń ṣọ̀fọ̀ kirinítorí ìnilára ọ̀tá?

3. Rán ìmọ́lẹ̀ rẹ ati òtítọ́ rẹ jáde,jẹ́ kí wọ́n máa tọ́ mi sọ́nà;jẹ́ kí wọ́n mú mi wá sí orí òkè mímọ́ rẹ,ati ibùgbé rẹ.

4. Nígbà náà ni n óo lọ sí ibi pẹpẹ Ọlọrun,àní, sọ́dọ̀ Ọlọrun, ayọ̀ ńlá mi.Èmi óo sì yìn ọ́ pẹlu hapu,Ọlọrun, Ọlọrun mi.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 43