Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 41:5-12 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Àwọn ọ̀tá mi ń ro ibi sí mi, wọ́n ń wí pé,“Nígbà wo ni yóo kú, tí orúkọ rẹ̀ yóo parẹ́?”

6. Tí ọ̀kan bá wá bẹ̀ mí wò,ọ̀rọ̀ tí kò lórí, tí kò nídìíni yóo máa sọ;bẹ́ẹ̀ ni ninu ọkàn rẹ̀, èrò ibi ni yóo máa gbà.Nígbà tí ó bá jáde,yóo máa rò mí kiri.

7. Gbogbo àwọn tí ó kórìíra mijọ ń sọ̀rọ̀ wújẹ́wújẹ́ nípa mi;ohun tó burú jùlọ ni wọ́n ń rò sí mi.

8. Wọ́n ń wí pé, “Àìsàn burúkú ti gbé e dálẹ̀;kò ní dìde mọ́ níbi tí ó dùbúlẹ̀ sí.”

9. Àní ọ̀rẹ́ kòríkòsùn mi tí mo gbẹ́kẹ̀lé,tí ó ń jẹun nílé mi,ó ti kẹ̀yìn sí mí.

10. Ṣugbọn, OLUWA, ṣàánú mi;gbé mi dìde, kí n lè san ẹ̀san fún un.

11. Kí n lè mọ̀ pé o fẹ́ràn mi,nígbà tí ọ̀tá kò bá borí mi.

12. O ti gbé mi ró nítorí ìwà pípé mi,o sì fi ẹsẹ̀ mi múlẹ̀ níwájú rẹ títí lae.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 41