Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 4:3-8 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Ṣugbọn kí ẹ mọ̀ dájú pé OLUWA ti ya olódodo sọ́tọ̀ fún ara rẹ̀,OLUWA yóo gbọ́ nígbà tí mo bá pè é.

4. Bí ó ti wù kí ẹ bínú tó, ẹ má dẹ́ṣẹ̀;ẹ bá ọkàn yín sọ̀rọ̀ lórí ibùsùn yín,kí ẹ sì dákẹ́ jẹ́ẹ́.

5. Ẹ rú ẹbọ òdodo,kí ẹ sì gbẹ́kẹ̀lé OLUWA.

6. Ọ̀pọ̀ eniyan ni ó ń bèèrè pé “Ta ni yóo ṣe wá ní oore?”OLUWA, tan ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ sí wa lára.

7. Ìwọ ti fi ayọ̀ kún ọkàn miju ayọ̀ àwọn tí ó rí ọpọlọpọ ọkà ati ọtí waini nígbà ìkórè.

8. N óo dùbúlẹ̀, n óo sì sùn ní alaafia,nítorí ìwọ OLUWA nìkan ni o mú mi wà láìléwu.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 4