Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 4:1-7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Dá mi lóhùn nígbà tí mo bá pè ọ́,Ọlọrun mi olùdániláre.Ìwọ ni o yọ mí nígbà tí mo wà ninu ìpọ́njú,ṣàánú mi, kí o sì gbọ́ adura mi.

2. Ẹ̀yin ọmọ eniyan, yóo ti pẹ́ tó, tí ẹ óo máa fi ojú ọlá mi gbolẹ̀,tí ẹ óo máa fẹ́ràn ọ̀rọ̀ asán, tí ẹ óo sì máa wá irọ́ kiri?

3. Ṣugbọn kí ẹ mọ̀ dájú pé OLUWA ti ya olódodo sọ́tọ̀ fún ara rẹ̀,OLUWA yóo gbọ́ nígbà tí mo bá pè é.

4. Bí ó ti wù kí ẹ bínú tó, ẹ má dẹ́ṣẹ̀;ẹ bá ọkàn yín sọ̀rọ̀ lórí ibùsùn yín,kí ẹ sì dákẹ́ jẹ́ẹ́.

5. Ẹ rú ẹbọ òdodo,kí ẹ sì gbẹ́kẹ̀lé OLUWA.

6. Ọ̀pọ̀ eniyan ni ó ń bèèrè pé “Ta ni yóo ṣe wá ní oore?”OLUWA, tan ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ sí wa lára.

7. Ìwọ ti fi ayọ̀ kún ọkàn miju ayọ̀ àwọn tí ó rí ọpọlọpọ ọkà ati ọtí waini nígbà ìkórè.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 4