Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 39:7-13 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Wàyí ò, OLUWA, kí ló kù tí mo gbójú lé?Ìwọ ni mo fẹ̀yìn tì.

8. Gbà mí ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ìrékọjá mi;má sọ mí di ẹni ẹ̀gàn lójú àwọn òmùgọ̀.

9. Mo dákẹ́, n kò ya ẹnu mi;nítorí pé ìwọ ni o ṣe é.

10. Dáwọ́ ẹgba rẹ dúró lára mi,mo ti fẹ́rẹ̀ kú nítorí ìyà tí o fi ń jẹ mí.

11. Nígbà tí o bá jẹ eniyan níyàpẹlu ìbáwí nítorí ẹ̀ṣẹ̀,ìwọ á ba ohun tí ó ṣọ̀wọ́n fún un jẹ́ bíi kòkòrò aṣọ.Dájúdájú, afẹ́fẹ́ lásán ni eniyan.

12. “OLUWA, gbọ́ adura mi,tẹ́tí sí igbe mi,má dágunlá sí ẹkún mi,nítorí pé àlejò rẹ, tí ń rékọjá lọ ni mo jẹ́;àjèjì sì ni mí, bíi gbogbo àwọn baba mi.

13. Mú ojú ìbáwí kúrò lára mi,kí inú mi lè dùn kí n tó kọjá lọ;àní, kí n tó ṣe aláìsí.”

Ka pipe ipin Orin Dafidi 39