Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 39:1-6 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Mo ní, “Èmi óo máa ṣọ́ra,kí n má baà fi ahọ́n mi dẹ́ṣẹ̀;n óo kó ẹnu mi ní ìjánu,níwọ̀n ìgbà tí àwọn eniyan burúkú bá wà nítòsí.”

2. Mo dákẹ́, n ò sọ nǹkankan;n ò tilẹ̀ dá sí ọ̀rọ̀ rere pàápàá;sibẹ ìpọ́njú mi ń pọ̀ sí i

3. ìdààmú dé bá ọkàn mi.Bí mo ti ń ronú, ọkàn mi dàrú;mo bá sọ̀rọ̀ jáde, mo ní:

4. “OLUWA, jẹ́ kí n mọ òpin ayé mi,ati ìwọ̀nba ọjọ́ ayé mi,kí n lè mọ̀ pé ayé mi ń sáré kọjá lọ.”

5. Wò ó, o ti ṣe ọjọ́ mi ní ìwọ̀n ìbú àtẹ́lẹwọ́ mélòó kan,ọjọ́ ayé mi kò sì tó nǹkankan ní ojú rẹ;dájúdájú, ọmọ eniyan dàbí afẹ́fẹ́ lásán.

6. Dájúdájú, eniyan ń káàkiri bí òjìji,asán sì ni gbogbo làálàá rẹ̀;eniyan a máa kó ọrọ̀ jọ ṣá,láìmọ ẹni tí yóo kó o lọ.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 39