Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 38:5-9 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Ọgbẹ́ mi ń kẹ̀, ó sì ń rùn,nítorí ìwà òmùgọ̀ mi,

6. Ìbànújẹ́ dorí mi kodò patapata,mo sì ń ṣọ̀fọ̀ kiri tọ̀sán-tòru.

7. Gbogbo ẹ̀gbẹ́ mi ń gbóná fòò,kò sí ibìkan tí ó gbádùn lára mi.

8. Àárẹ̀ mú mi patapata, gbogbo ara sì wó mi;mò ń kérora nítorí ẹ̀dùn ọkàn mi.

9. OLUWA, gbogbo ìfẹ́ ọkàn mi ni o mọ̀,ìmí ẹ̀dùn mi kò sì pamọ́ fún ọ.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 38