Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 36:3-12 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Ọ̀rọ̀ ìkà ati ẹ̀tàn ni ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀.Ó ti dáwọ́ ire ṣíṣe dúró;kò sì hu ìwà ọlọ́gbọ́n mọ́.

4. A máa pète ìkà lórí ibùsùn rẹ̀;a máa rin ọ̀nà tí kò tọ́;kò sì kórìíra ibi.

5. OLUWA, ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ga kan ọ̀run;òtítọ́ rẹ sì kan ojú ọ̀run.

6. Òtítọ́ rẹ dàbí òkè ńlá;ìdájọ́ rẹ sì jìn bí ibú omi.OLUWA, àtènìyàn, àtẹranko ni ò ń gbàlà.

7. Ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ níye lórí pupọ, Ọlọrun!Àwọn ọmọ eniyan a máa sá sí abẹ́ òjìji ìyẹ́ apá rẹ.

8. Wọ́n ń rí oúnjẹ jẹ ní àjẹyó ní ilé rẹ;nǹkan mímu tí ń ṣàn bí odò,ni o sì ń fún wọn mu.

9. Nítorí pé lọ́dọ̀ rẹ ni orísun ìyè wà;ninu ìmọ́lẹ̀ rẹ ni a ti ń rí ìmọ́lẹ̀.

10. Túbọ̀ máa fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀han àwọn tí ó mọ̀ ọ́,sì máa fi òdodo rẹ han àwọn ọlọ́kàn mímọ́.

11. Má jẹ́ kí àwọn agbéraga borí mi,má sì jẹ́ kí àwọn eniyan burúkú lé mi kúrò.

12. Ẹ wo àwọn aṣebi níbi tí wọ́n ṣubú sí;wọ́n dà wólẹ̀, wọn kò sì le dìde.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 36