Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 36:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹ̀ṣẹ̀ ń gbin lọ́kàn eniyan burúkú,kò sí ìbẹ̀rù Ọlọrun ninu èrò tirẹ̀.

2. Nítorí pé lọ́kàn rẹ̀ a máa pọ́n ara rẹ̀,pé kò sí ẹni tí ó lè rí ẹ̀ṣẹ̀ òun,ká tó wá sọ pé yóo dá òun lẹ́bi.

3. Ọ̀rọ̀ ìkà ati ẹ̀tàn ni ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀.Ó ti dáwọ́ ire ṣíṣe dúró;kò sì hu ìwà ọlọ́gbọ́n mọ́.

4. A máa pète ìkà lórí ibùsùn rẹ̀;a máa rin ọ̀nà tí kò tọ́;kò sì kórìíra ibi.

5. OLUWA, ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ga kan ọ̀run;òtítọ́ rẹ sì kan ojú ọ̀run.

6. Òtítọ́ rẹ dàbí òkè ńlá;ìdájọ́ rẹ sì jìn bí ibú omi.OLUWA, àtènìyàn, àtẹranko ni ò ń gbàlà.

7. Ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ níye lórí pupọ, Ọlọrun!Àwọn ọmọ eniyan a máa sá sí abẹ́ òjìji ìyẹ́ apá rẹ.

8. Wọ́n ń rí oúnjẹ jẹ ní àjẹyó ní ilé rẹ;nǹkan mímu tí ń ṣàn bí odò,ni o sì ń fún wọn mu.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 36