Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 35:23-28 BIBELI MIMỌ (BM)

23. Paradà, OLUWA, jí gìrì sí ọ̀ràn mi,gbèjà mi, Ọlọrun mi, ati OLUWA mi!

24. Dá mi láre, OLUWA, Ọlọrun mi, gẹ́gẹ́ bí òdodo rẹ;má sì jẹ́ kí wọ́n yọ̀ mí!

25. Má jẹ́ kí wọ́n wí láàrin ara wọn pé,“Ìn hín ìn, ọwọ́ wa ba ohun tí a fẹ́!”Má jẹ́ kí wọn wí pé,“A rẹ́yìn ọ̀tá wa.”

26. Jẹ́ kí ojú ti gbogbo àwọn tí ń yọ̀ pé ìpọ́njú dé bá mi;kí ìdààmú bá wọn;bá mi da aṣọ ìtìjú ati ẹ̀tẹ́ bo àwọn tí ń gbé àgbéré sí mi.

27. Kí àwọn tí ń wá ìdáláre mimáa hó ìhó ayọ̀, kí inú wọn sì máa dùn,kí wọ́n máa wí títí ayé pé,“OLUWA tóbi,inú rẹ̀ dùn sí alaafia àwọn iranṣẹ rẹ̀.”

28. Nígbà náà ni n óo máa sọ̀rọ̀ òdodo rẹ,n óo sì máa yìn ọ́ tọ̀sán-tòru.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 35