Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 34:6-14 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Olùpọ́njú ké pe OLUWA, OLUWA gbọ́ ohùn rẹ̀,ó sì gbà á ninu gbogbo ìpọ́njú rẹ̀.

7. Angẹli OLUWA yí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ká,a sì máa gbà wọ́n.

8. Tọ́ ọ wò, kí o sì rí i pé rere ni OLUWA!Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bá sá di í!

9. Ẹ bẹ̀rù OLUWA, ẹ̀yin eniyan mímọ́ rẹ̀,nítorí pé kò sí àìní fún àwọn tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀!

10. Àwọn ọmọ kinniun a máa ṣe aláìní,ebi a sì máa pa wọ́n;ṣugbọn àwọn tí wọ́n bá ń wá OLUWAkò ní ṣe aláìní ohun rere kankan.

11. Ẹ wá, ẹ̀yin ọmọ, ẹ tẹ́tí sí mi,n óo kọ yín ní ìbẹ̀rù OLUWA.

12. Ta ni ń fẹ́ ìyè ninu yín,tí ń fẹ́ ẹ̀mí gígùn,tí ó fẹ́ pẹ́ láyé?

13. Ẹ ṣọ́ ẹnu yín, ẹ má sọ̀rọ̀ burúkú,ẹ má sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn ti ẹnu yín jáde.

14. Ẹ yàgò fún ibi, rere ni kí ẹ máa ṣe;ẹ máa wá alaafia, kí ẹ sì máa lépa rẹ̀.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 34