Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 34:12-19 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Ta ni ń fẹ́ ìyè ninu yín,tí ń fẹ́ ẹ̀mí gígùn,tí ó fẹ́ pẹ́ láyé?

13. Ẹ ṣọ́ ẹnu yín, ẹ má sọ̀rọ̀ burúkú,ẹ má sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn ti ẹnu yín jáde.

14. Ẹ yàgò fún ibi, rere ni kí ẹ máa ṣe;ẹ máa wá alaafia, kí ẹ sì máa lépa rẹ̀.

15. OLUWA ń ṣọ́ àwọn olódodo,Ó sì ń dẹ etí sí igbe wọn.

16. OLUWA fojú sí àwọn aṣebi lára,láti pa wọ́n rẹ́, kí á má sì ṣe ranti wọn mọ́ lórí ilẹ̀ ayé.

17. Nígbà tí olódodo bá kígbe fún ìrànlọ́wọ́, OLUWA a máa gbọ́,a sì máa gbà wọ́n kúrò ninu gbogbo ìyọnu wọn.

18. OLUWA wà nítòsí àwọn tí ọkàn wọn bàjẹ́,a sì máa gba àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn là.

19. Ìpọ́njú olódodo a máa pọ̀;ṣugbọn OLUWA a máa kó o yọ ninu gbogbo wọn.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 34