Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 33:1-6 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹ máa yọ̀ ninu OLUWA, ẹ̀yin olódodo!Yíyin OLUWA ni ó yẹ ẹ̀yin olóòótọ́.

2. Ẹ fi gòjé yin OLUWA,ẹ fi hapu olókùn mẹ́wàá kọ orin sí i.

3. Ẹ kọ orin titun sí i,ẹ fi ohun èlò ìkọrin olókùn dárà,kí ẹ sì hó ìhó ayọ̀.

4. Nítorí ọ̀rọ̀ OLUWA dúró ṣinṣin;òtítọ́ sì ni ó fi ń ṣe gbogbo iṣẹ́ rẹ̀.

5. OLUWA fẹ́ràn òdodo ati ẹ̀tọ́;ayé kún fún ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀.

6. Ọ̀rọ̀ ni OLUWA fi dá ojú ọ̀run,èémí ẹnu rẹ̀ ni ó sì fi dá oòrùn, òṣùpá, ati àwọn ìràwọ̀.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 33