Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 32:1-11 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí a dárí ìrékọjá rẹ̀ jì,tí a bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀.

2. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí OLUWA kò ka ẹ̀ṣẹ̀ sí lọ́rùn,tí ẹ̀tàn kò sì sí ninu ọkàn rẹ̀.

3. Nígbà tí n kò jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi,ó rẹ̀ mí wá láti inú,nítorí kíkérora tí mò ń kérora ní gbogbo ìgbà.

4. Nítorí tọ̀sán-tòru ni o fi ń jẹ mí níyà;gbogbo agbára mi ló lọ háú,bí omi tíí gbẹ lákòókò ẹ̀ẹ̀rùn.

5. Mo jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi fún ọ;n kò sì fi àìdára mi pamọ́ fún ọ.Mo ní, “Èmi óo jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi fún Oluwa,”o sì dáríjì mí.

6. Nítorí náà, kí gbogbo olódodo máa gbadura sí ọ;ní àkókò tí ìpọ́njú bá ń yí lura wọn bí ìṣàn omi ńlá,kò ní dé ọ̀dọ̀ wọn.

7. Ìwọ ni ibi ìsásí mi;o pa mí mọ́ kúrò ninu ìṣòro;o sì fi ìgbàlà yí mi ká.

8. N óo kọ́ ọ, n óo sì tọ́ ọ sí ọ̀nà tí o óo rìn;n óo máa gbà ọ́ ní ìmọ̀ràn;n óo sì máa mójútó ọ.

9. Má ṣe dàbí ẹṣin tabi ìbaaka,tí kò ni ọgbọ́n ninu,tí a gbọdọ̀ kó ìjánu sí lẹ́nukí ó tó lè gbọ́ ti oluwa rẹ̀.

10. Ìrora pọ̀ fún àwọn eniyan burúkú,ṣugbọn ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ni ó yí àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé OLUWA ká.

11. Ẹ máa yọ̀ ninu OLUWA;ẹ fò fún ayọ̀, ẹ̀yin olódodo;kí ẹ sì hó fún ayọ̀, gbogbo ẹ̀yin ọlọ́kàn mímọ́.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 32