Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 30:4-12 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Ẹ kọ orin ìyìn sí OLUWA, ẹ̀yin olùfọkànsìn rẹ̀,kí ẹ sì fi ọpẹ́ fún orúkọ mímọ́ rẹ̀.

5. Nítorí pé fún ìgbà díẹ̀ ni ibinu rẹ̀,ṣugbọn títí ayé ni ojurere rẹ̀;eniyan lè máa sọkún títí di alẹ́,ṣugbọn ayọ̀ ń bọ̀ fún un lówùúrọ̀.

6. Nígbà tí ara rọ̀ mí,mo wí ninu ọkàn mi pé,kò sí ohun tí ó lè mì mí laelae.

7. Nípa ojurere rẹ, OLUWA,o ti fi ìdí mi múlẹ̀ bí òkè ńlá;ṣugbọn nígbà tí o fi ojú pamọ́ fún mi,ìdààmú dé bá mi.

8. Ìwọ ni mò ń ké pè, OLUWA,OLUWA, ìwọ ni mò ń bẹ̀.

9. Anfaani wo ló wà ninu pé kí n kú?Èrè wo ló wà ninu pé kí n wọ inú kòtò?Ṣé erùpẹ̀ lè yìn ọ́?Ṣé ó lè sọ nípa òdodo rẹ?

10. Gbọ́ OLUWA, kí o sì ṣàánú mi,OLUWA, ràn mí lọ́wọ́.

11. O ti bá mi sọ ọ̀fọ̀ mi di ijó,o ti bọ́ aṣọ ọ̀fọ̀ kúrò lára mi,o sì ti dì mí ní àmùrè ayọ̀,

12. kí ọkàn mi lè máa yìn ọ́ láìdákẹ́.OLUWA Ọlọrun mi, n óo máa fi ọpẹ́ fún ọ títí lae.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 30