Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 3:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA, àwọn ọ̀tá mi pọ̀ pupọ!Ọ̀pọ̀ ni ó ń dìde sí mi!

2. Ọpọlọpọ ni àwọn tí ń sọ kiri pé,Ọlọrun kò ní gbà mí sílẹ̀!

3. Ṣugbọn ìwọ OLUWA ni ààbò mi,ògo mi, ati ẹni tí ó fún mi ní ìgboyà.

4. Mo ké pe OLUWA,ó sì dá mi lóhùn láti òkè mímọ́ rẹ̀ wá.

5. Mo dùbúlẹ̀, mo sùn, mo sì jí,nítorí OLUWA ni ó ń gbé mi ró.

6. Ẹgbẹẹgbẹrun ọ̀tá tó yí mi kákò le bà mí lẹ́rù.

7. Dìde, OLUWA, gbà mí, Ọlọrun mi!Nítorí ìwọ ni o lu gbogbo àwọn ọ̀tá mi bolẹ̀,tí o sì ṣẹgun àwọn eniyan burúkú.

8. OLUWA níí gbani,kí ibukun rẹ̀ kí ó wà lórí àwọn eniyan rẹ̀.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 3