Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 27:7-14 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Gbọ́ OLUWA, nígbà tí mo bá ń kígbe pè ọ́;ṣàánú mi kí o sì dá mi lóhùn.

8. Nígbà tí o wí pé, “Ẹ máa wá ojú mi.”Ọkàn mi dá ọ lóhùn pé, “Ojú rẹ ni n óo máa wá, OLUWA,

9. má fi ojú pamọ́ fún mi!”Má fi ibinu lé èmi iranṣẹ rẹ kúrò,ìwọ tí o ti ń ràn mí lọ́wọ́,má ta mí nù, má sì ṣá mi tì,Ọlọrun ìgbàlà mi.

10. Bí baba ati ìyá mi tilẹ̀ kọ̀ mí sílẹ̀,OLUWA yóo tẹ́wọ́gbà mí.

11. Kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ, OLUWA,kí o sì tọ́ mi sí ọ̀nà títẹ́jú rẹ,nítorí àwọn ọ̀tá mi.

12. Má fi mí lé ìfẹ́ àwọn ọ̀tá mi lọ́wọ́;nítorí pé àwọn ẹlẹ́rìí èké dìde sí mi,ètè wọn sì kún fún ọ̀rọ̀ ìkà.

13. Mo gbàgbọ́ pé n óo rí oore OLUWA gbàní ilẹ̀ alààyè.

14. Dúró de OLUWA,ṣe bí akin, kí o sì mú ọkàn gírí,àní, dúró de OLUWA.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 27