Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 26:6-12 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Ọwọ́ mi mọ́, n kò ní ẹ̀bi, OLUWA,mo sì ń jọ́sìn yí pẹpẹ rẹ ká.

7. Mò ń kọ orin ọpẹ́ sókè,mo sì ń ròyìn iṣẹ́ ìyanu rẹ.

8. OLUWA, mo fẹ́ràn ilé rẹ, tí ò ń gbé,ati ibi tí ògo rẹ wà.

9. Má pa mí run pẹlu àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,má sì gba ẹ̀mí mi pẹlu ti àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ìpànìyàn,

10. àwọn tí ọwọ́ wọn kún fún iṣẹ́ ibi,tí ọwọ́ ọ̀tún wọn sì kún fún àbẹ̀tẹ́lẹ̀.

11. Ṣugbọn ní tèmi, èmi ń rìn ninu ìwà pípé;rà mí pada, kí o sì ṣàánú mi.

12. Mo dúró lórí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú;láwùjọ ọ̀pọ̀ eniyan ni n óo máa yin OLUWA.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 26