1. Dá mi láre, OLUWA,nítorí ninu ìwà pípé ni mò ń rìn,mo sì gbẹ́kẹ̀lé OLUWA láìṣiyèméjì.
2. Yẹ̀ mí wò, OLUWA, dán mi wò;yẹ inú mi wò, sì ṣe akiyesi ọkàn mi.
3. Nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ni mo tẹjúmọ́,mo sì ń fi òtítọ́ bá ọ rìn.
4. N kò jókòó ti àwọn èké,n kò sì gba ìmọ̀ràn àwọn ẹlẹ́tàn;
5. mo kórìíra wíwà pẹlu àwọn aṣebi,n kò sì jẹ́ bá àwọn eniyan burúkú da nǹkan pọ̀.
6. Ọwọ́ mi mọ́, n kò ní ẹ̀bi, OLUWA,mo sì ń jọ́sìn yí pẹpẹ rẹ ká.
7. Mò ń kọ orin ọpẹ́ sókè,mo sì ń ròyìn iṣẹ́ ìyanu rẹ.
8. OLUWA, mo fẹ́ràn ilé rẹ, tí ò ń gbé,ati ibi tí ògo rẹ wà.
9. Má pa mí run pẹlu àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,má sì gba ẹ̀mí mi pẹlu ti àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ìpànìyàn,