Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 26:1-7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Dá mi láre, OLUWA,nítorí ninu ìwà pípé ni mò ń rìn,mo sì gbẹ́kẹ̀lé OLUWA láìṣiyèméjì.

2. Yẹ̀ mí wò, OLUWA, dán mi wò;yẹ inú mi wò, sì ṣe akiyesi ọkàn mi.

3. Nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ni mo tẹjúmọ́,mo sì ń fi òtítọ́ bá ọ rìn.

4. N kò jókòó ti àwọn èké,n kò sì gba ìmọ̀ràn àwọn ẹlẹ́tàn;

5. mo kórìíra wíwà pẹlu àwọn aṣebi,n kò sì jẹ́ bá àwọn eniyan burúkú da nǹkan pọ̀.

6. Ọwọ́ mi mọ́, n kò ní ẹ̀bi, OLUWA,mo sì ń jọ́sìn yí pẹpẹ rẹ ká.

7. Mò ń kọ orin ọpẹ́ sókè,mo sì ń ròyìn iṣẹ́ ìyanu rẹ.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 26