Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 25:13-22 BIBELI MIMỌ (BM)

13. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ yóo ní ọpọlọpọ ọrọ̀,àwọn ọmọ rẹ̀ ni yóo sì jogún ilẹ̀ náà.

14. Àwọn tí ó bá bẹ̀rù OLUWA ni OLUWA ń mú ní ọ̀rẹ́,a sì máa fi majẹmu rẹ̀ hàn wọ́n.

15. OLUWA ni mò ń wò lójú nígbà gbogbo,nítorí òun ni yóo yọ ẹsẹ̀ mi kúrò ninu àwọ̀n.

16. Kọjú sí mi kí o sì ṣàánú mi;nítorí n kò lẹ́nìkan, ojú sì ń pọ́n mi.

17. Mú ìdààmú ọkàn mi kúrò;kí o sì yọ mí ninu gbogbo ìpọ́njú mi.

18. Wo ìpọ́njú ati ìdààmú mi,kí o sì dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí.

19. Wo iye ọ̀tá tí èmi nìkan ní,ati irú ìkórìíra ìkà tí wọ́n kórìíra mi.

20. Pa mí mọ́, kí o sì gbà mí;má jẹ́ kí ojú kí ó tì mí,nítorí ìwọ ni mo sá di.

21. Nítorí pípé mi ati òdodo mi, pa mí mọ́,nítorí pé ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé.

22. Ọlọrun, ra Israẹli pada,kúrò ninu gbogbo ìyọnu rẹ̀.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 25