Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 24:1-5 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA ló ni ilẹ̀ ati gbogbo ohun tí ó wàninu rẹ̀,òun ló ni ayé, ati gbogbo àwọn tíń gbé inú rẹ̀;

2. nítorí pé òun ló fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ lórí òkun,ó sì gbé e kalẹ̀ lórí ìṣàn omi.

3. Ta ló lè gun orí òkè OLUWA lọ?Ta ló sì lè dúró ninu ibi mímọ́ rẹ̀?

4. Ẹni tí ọwọ́ rẹ̀ mọ́, tí inú rẹ̀ sì funfun,tí kò gbẹ́kẹ̀lé oriṣa lásánlàsàn,tí kò sì búra èké.

5. Òun ni yóo rí ibukun gbà lọ́dọ̀ OLUWA,tí yóo sì rí ìdáláre gbà lọ́wọ́ Ọlọrun, Olùgbàlà rẹ̀.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 24