Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 22:6-20 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Ṣugbọn kòkòrò lásán ni mí, n kì í ṣe eniyan;ayé kẹ́gàn mi, gbogbo eniyan sì ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà.

7. Gbogbo àwọn tí ó rí mi ní ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́;wọ́n ń yọ ṣùtì sí mi;wọ́n sì ń mi orí pé,

8. “Ṣebí OLUWA ni ó fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ lé lọ́wọ́;kí OLUWA ọ̀hún yọ ọ́, kí ó sì gbà á là,ṣebí inú rẹ̀ dùn sí i!”

9. Bẹ́ẹ̀ sì ni ìwọ ni o mú mi jáde láti inú ìyá mi;ìwọ ni o sì mú mi wà láìséwu nígbà tí mo wà ní ọmọ ọmú.

10. Ìwọ ni wọ́n bí mi lé lọ́wọ́;ìwọ ni Ọlọrun miláti ìgbà tí ìyá mi ti bí mi.

11. Má jìnnà sí mi,nítorí pé ìyọnu wà nítòsí,kò sì sí ẹni tí yóo ràn mí lọ́wọ́.

12. Àwọn ọ̀tá yí mi ká bí akọ mààlúù,wọ́n yí mi ká bí akọ mààlúù Baṣani tó lágbára.

13. Wọ́n ya ẹnu wọn sí mi bí kinniun,bí kinniun tí ń dọdẹ kiri tí ń bú ramúramù.

14. Agbára mi ti lọ, ó ti ṣàn dànù bí omi,gbogbo egungun mi ti yẹ̀ lóríkèéríkèé;ọkàn mi dàbí ìda, ó ti yọ́.

15. Okun inú mi ti gbẹ bí àpáàdì,ahọ́n mi sì ti lẹ̀ mọ́ mi lẹ́nu;o ti fi mí sílẹ̀ sinu eruku isà òkú.

16. Àwọn eniyan burúkú yí mi ká bí ajá;àwọn aṣebi dòòyì ká mi;wọ́n fa ọwọ́ ati ẹsẹ̀ mi ya.

17. Mo lè ka gbogbo egungun miwọ́n tẹjúmọ́ mi; wọ́n ń fojú burúkú wò mí.

18. Wọ́n pín aṣọ mi láàrin ara wọn,wọ́n ṣẹ́ gègé nítorí ẹ̀wù mi.

19. Ṣugbọn ìwọ, OLUWA, má jìnnà sí mi!Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ mi, ṣe gírí láti ràn mí lọ́wọ́!

20. Gba ẹ̀mí mi lọ́wọ́ idà,gbà mí lọ́wọ́ àwọn ajá!

Ka pipe ipin Orin Dafidi 22